Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí. A gbé àgọ́ kan dìde. Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn. Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́. Àti lẹ́yìn aṣọ ìkélé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní ibi mímọ́ jùlọ; tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú; àti lórí àpótí ni àwọn kérúbù ògo ti i ṣíji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan. Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkúgbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn. Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìṣìnà àwọn ènìyàn. Ẹ̀mí mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà ibi mímọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkínní bá sì dúró, (Èyí tí i ṣe àpẹẹrẹ fún ìgbà ìsinsin yìí). Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé, Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí í ṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe.
Kà Heberu 9
Feti si Heberu 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heberu 9:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò