Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”
Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.
Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli (Ọlọ́run Beteli), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.
Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú, a sì sin ín sábẹ́ igi óákù ní ìsàlẹ̀ Beteli: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bakuti (Óákù Ẹkún).
Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un. Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Israẹli (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli.
Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai); máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.” Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.
Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu (wáìnì) ní orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú. Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli.