ỌLỌRUN si wi fun Jakobu pe, Dide goke lọ si Beteli ki o si joko nibẹ̀, ki o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, fun Ọlọrun, ti o farahàn ọ, nigbati iwọ sá kuro niwaju Esau, arakunrin rẹ.
Nigbana ni Jakobu wi fun awọn ara ile rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ti o wà li ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mú àjeji oriṣa ti o wà lọwọ nyin kuro, ki ẹnyin ki o si sọ ara nyin di mimọ́, ki ẹnyin ki o si pa aṣọ nyin dà:
Ẹ si jẹ ki a dide, ki a si goke lọ si Beteli; nibẹ̀ li emi o si gbé tẹ́ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ti o da mi li ohùn li ọjọ́ ipọnju mi, ẹniti o si wà pẹlu mi li àjo ti mo rè.
Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu.
Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu.
Bẹ̃ni Jakobu si wá si Lusi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, eyinì ni Beteli, on ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀.
O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni El-bet-el: nitori pe nibẹ̀ li Ọlọrun tọ̀ ọ wá, nigbati o sá kuro niwaju arakunrin rẹ̀.
Ṣugbọn Debora olutọ́ Rebeka kú, a si sin i nisalẹ Beteli labẹ igi oaku kan: orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Alloni-bakutu.
Ọlọrun si tún farahàn Jakobu, nigbati o ti Padan-aramu bọ̀, o si sure fun u.
Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli.
Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá;
Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun.
Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ.
Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀.
Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.