Gẹnẹsisi 29:16-25

Gẹnẹsisi 29:16-25 YCB

Wàyí o, Labani ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rakeli. Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rakeli ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra. Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.” Labani sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí náà wà ní ọ̀dọ̀ mi.” Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀. Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.” Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú Lea tọ Jakọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Labani sì fi Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Lea gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́. Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?”