Gẹnẹsisi 28:20-22

Gẹnẹsisi 28:20-22 YCB

Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà OLúWA ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”