Galatia Ìfáàrà
Ìfáàrà
Paulu tí wàásù fún àwọn olùgbé agbègbè Galatia ní ọ̀nà ìrìnàjò iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ́ kìn-ín-ní nínú ìwé Ìṣe àwọn Aposteli 13.14–14.23. Ní kété tí ó fì ibẹ̀ sílẹ̀, àwọn Kristiani Júù kan dé ibẹ̀ láti fi àáké kọ́rí pé ọ̀ràn dandan ni fún àwọn Kristiani tí kì í ṣe Júù láti tẹ̀lé òfin tí Mose fi lélẹ̀ kí wọn tó lè rí ìgbàlà. Paulu kọ̀wé láti fi dẹ́kun àṣìṣe yìí nípa fífi Abrahamu tó tí gbé ní irínwó ọdún sẹ́yìn kí òfin tó wáyé hàn bí ẹni tí ó rí ìgbàlà nípa ìgbàgbọ́ nínú ìhìnrere, báwo ni a ṣe lè sọ pé òfin ni ó lè gba ènìyàn là tàbí mú kí ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Jesu di pípé? Ó sọ̀rọ̀ lórí irú ìgbé ayé tó yẹ ọmọlẹ́yìn Kristi.
Paulu fi gbogbo agbára dáàbò bo òtítọ́ ìhìnrere, èyí tó sọ pé ènìyàn ń rí ìgbàlà nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi nìkan. Ìkọ́ni tó bá yàtọ̀ sí èyí jẹ́ àyípo òtítọ́ Ọlọ́run (1.7). A sọ wá di ẹni títọ́ níwájú Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ (2.16) a sì padà di ènìyàn Ọlọ́run bí Abrahamu nípa ìgbàgbọ́ kan náà (3.7). Nítorí pé a ní òmìnira nínú Kristi, a gbọdọ̀ fi ara wa fún Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run (5.16), kí a sì fẹ́ràn ẹnìkejì wa gẹ́gẹ́ bí ara wa (5.14).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Paulu dáàbò bo ara rẹ̀ àti ìhìnrere 1.1–2.21.
ii. Òmìnira kúrò nínú ìdè òfin 3.1-24.
iii. Ìyìn rere ga ju òfin lọ 3.25–4.31.
iv. Òmìnira àwọn onígbàgbọ́ 5.1-26.
v. Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú 6.1-18.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Galatia Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.