Ará, bí a tilẹ̀ mú ènìyàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkára rẹ̀ máa kíyèsára, kí a má ba à dán ìwọ náà wò pẹ̀lú. Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ. Nítorí bí ènìyàn kan bá ń ro ara rẹ̀ sí ẹnìkan, nígbà tí kò jẹ́ nǹkan, ó ń tan ara rẹ̀ jẹ. Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà, ohun ìmú-ṣogo rẹ̀ yóò jẹ́ nínú ti ara rẹ̀ nìkan, kì yóò sì jẹ nínú ti ọmọnìkejì rẹ̀. Nítorí pé olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí a ń kọ́ nínú ọ̀rọ̀ náà máa pèsè ohun rere gbogbo fún ẹni tí ń kọ́ni. Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká. Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.
Kà Galatia 6
Feti si Galatia 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Galatia 6:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò