Galatia 5:16-24

Verse Images for Galatia 5:16-24

Galatia 5:16-24 - Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.
Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.Galatia 5:16-24 - Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.
Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Galatia 5:16-24