“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí:
“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,
o kún fún ọgbọ́n,
o sì pé ní ẹwà.
Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;
onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;
sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,
àti jasperi, safire, emeradi,
turikuoṣe, àti karbunkili, àti wúrà,
ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,
láti ara wúrà,
ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
A fi ààmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,
torí èyí ni mo fi yàn ọ́.
Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;
ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná,
Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,
láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,
títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,
ìwọ kún fún ìwà ipá;
ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.
Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,
bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.
Èmi sì pa ọ run,
ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
Ọkàn rẹ gbéraga,
nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,
ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.
Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,
láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,
èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,
lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”