Esekiẹli 14:3-4

Esekiẹli 14:3-4 YCB

“Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn; Èmi yóò ha jẹ́ kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi rárá bí? Nítorí náà, sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tó gbé òrìṣà sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, tí ó sì wá sọ́dọ̀ wòlíì; Èmi OLúWA fúnra mi ni yóò dá ẹni tí ó wa lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ.