Esteri Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ kí a mọ àkọsílẹ̀ àsè Purimu lọ́dọọdún àti ìrántí ìtúsílẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn Júù ní, ní ìgbà ìṣèjọba Ahaswerusi. Ó jẹ́ kí a mọ̀ ààmì ìfojúwò àti ẹ̀tọ́ fún olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Ìjà tó wà láàrín Israẹli àti Ameleki, tó ti bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà Eksodu, tún tẹ̀síwájú nínú ìtàn Israẹli. Èyí tí ó jẹ́ àtakò àkọ́kọ́ fún Israẹli lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ ẹ wọn láti Ejibiti, lẹ́yìn ìgbà yìí ni Hamani gbèrò láti pa wọ́n run. Nítorí pé àwọn Júù jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run yàn, ó rán àánú sí wọn, ó ba àkọsílẹ̀ Hamani ti ó ṣètò láti pa wọ́n run jẹ́.
Àsè jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn kókó ìwé Esteri. Esteri rí ojúrere ọba Ahaswerusi nípa àsè tí ó sè, èyí tí ó mú kó di ayaba, tí ó sì jẹ́ kó rí ojúrere gbà fún àwọn ènìyàn rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Esteri di Ayaba 1.1–2.23.
ii. Hamani dìtẹ̀ mọ́ àwọn Júù 3.1–5.14.
iii. Wọ́n pa Hamani 6.1–7.10.
iv. Ìṣẹ́gun àwọn Júù lórí àwọn ọ̀tá wọn 8.1–10.3.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esteri Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.