Daniẹli 2:24-35

Daniẹli 2:24-35 YCB

Nígbà náà ni Daniẹli tọ́ Arioku lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Babeli run, Daniẹli wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Babeli run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sísọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.” Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.” Ọba béèrè lọ́wọ́ Daniẹli ẹni tí a tún ń pè ní Belṣassari pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?” Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí: “Ọba, bí ìwọ ṣe sùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àṣírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ. Ṣùgbọ́n fún èmi, a fi àṣírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀. “Ìwọ ọba ń wo, ère ńlá kan tí ó dúró níwájú rẹ, ère náà ga, ó sì dára láti wò, ìrísí i rẹ̀ ba ni lẹ́rù jọjọ. Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ, àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.