Kolose Ìfáárà
Ìfáárà
Paulu kọ lẹ́tà rẹ̀ yìí ní ẹ̀wọ̀n ní Romu sí ìlú tí kò tí ì dé rí. Ó mọ̀ nípa àwọn onígbàgbọ́ wọ̀nyí nígbà tó ń gbé ní Efesu nínú ìrìnàjò iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ kejì. Ọ̀rọ̀ náà jẹ ẹ́ lógún nísinsin yìí nítorí àwọn ìlànà ìbọ̀rìṣà tó ǹ wọ inú ilé Ọlọ́run. Èrò tó ń yọ àwọn ará Kolose lẹ́nu ni sé, wíwo ìràwọ̀, idán pípa àti ìbọ̀rìṣà pọ̀, èyí tó jẹ́ kí wọ́n rẹ Kristi sílẹ̀, tí wọ́n sì ń fiwé angẹli. Paulu kọ̀wé láti fi yé wọn pé Kristi ga ju àwọn ohun tí wọ́n ń fi díwọ̀n rẹ̀. Kristi kan náà ni Ọlọ́run tó ní ìjọba Ọlọ́run ní ìkáwọ́. (2.9). Ìwé yìí túnṣe àkíyèsí nípa ìgbé ayé Ọlọ́run nínú Kristi.
Nínú lẹ́tà pàtàkì yìí, Paulu ṣe àwíjàre tó fi Kristi hàn bí ẹni mímọ́ àti ẹni tó ní ògo jùlọ, òun ní ohun gbogbo, nínú rẹ̀ ni onígbàgbọ́ ti rí ohun gbogbo tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wọn gbà. Paulu kìlọ̀ pé kò yẹ kí a ṣi àwọn onígbàgbọ́ lọ́nà nípa ìwà òmùgọ̀ àti ọgbọ́n ẹ̀tàn àwọn ènìyàn (2.8). Ìlànà fún ìgbé ayé onígbàgbọ́ tó fi agbára ti Ọlọ́run fún ènìyàn hàn àti ayọ̀ tí onígbàgbọ́ lè ní nípa ṣíṣe àmúlò àwọn ohun tí Kristi ti pèsè sílẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ Paulu 1.1-14.
ii. Ògo Kristi 1.15–2.3.
iii. Ìkìlọ̀ nípa ìgbàgbọ́ ẹ̀tàn 2.4-23.
iv. Ìlànà ìgbé ayé onígbàgbọ́ 3.1–4.1.
v. Ọ̀rọ̀ ìyànjú lórí gbígba àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìgbẹ̀yìn 4.2-18.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Kolose Ìfáárà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.