Kolose 3:14-17

Kolose 3:14-17 YCB

Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé. Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.