Ìṣe àwọn Aposteli 8:9-25

Ìṣe àwọn Aposteli 8:9-25 YCB

Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun. Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bu ọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ ńlá.” Wọ́n bu ọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Filipi gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jesu Kristi, a bamitiisi wọn. Simoni tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bamitiisi rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú Filipi, ó wo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Filipi ṣe, ẹnu sì yà á. Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn. Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́: nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni. Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run! Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run. Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́. Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.” Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.” Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìhìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.