Ìṣe àwọn Aposteli 19:1-12

Ìṣe àwọn Aposteli 19:1-12 YCB

Nígbà ti Apollo wà ni Kọrinti, ti Paulu kọjá lọ sí apá òkè ìlú, ó sì wá sí Efesu: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan; o wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.” Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamitiisi wo ni a bamitiisi yín sí?” Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitiisi tí Johanu.” Paulu sí wí pé, “Nítòótọ́, ní Johanu fi bamitiisi tí ìrònúpìwàdà bamitiisi, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kristi Jesu.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa. Nígbà tí Paulu sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá. Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki. Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.