3 Johanu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Lẹ́tà kékeré yìí jẹ́ àkọsílẹ̀ Aposteli Johanu sí ọ̀rẹ́ rẹ ọ̀wọ́n Gaiusi, ó gbà á ní ìyànjú láti ran àwọn tí ń tan ìhìnrere kalẹ̀ lọ́wọ́, àwọn tí ń wàásù òtítọ́. Ó kìlọ̀ fún Gaiusi nípa àwọn ènìyàn bí í Diotirefe tí ó kọ̀ láti ran ìtànkálẹ̀ ìhìnrere lọ́wọ́, ó sì gbé oríyìn fún Demetriusi fún ìrànlọ́wọ́ tí ó ṣe.
Kristiani ní láti ran ara wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Kristi. Láìṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣiṣẹ́ fún èṣù tó ń wá ọ̀nà láti pa àwọn Kristiani run. Johanu tẹnumọ́ ọn pé gbogbo onígbàgbọ́ gbọdọ̀ di ara kan náà nínú Kristi àti pé wọn gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ìre gbogbo ènìyàn.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìfáàrà 1-4.
ii. Kristiani àti àlejò ṣíṣe 5-8.
iii. Iṣẹ́ ibi Diotirefe 9-11.
iv. Iṣẹ́ rere Demetriusi 12.
v. Àkíyèsí Ìparí 13-14.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

3 Johanu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀