2 Tẹsalonika Ìfáàrà

Ìfáàrà
Bóyá lẹ́tà Paulu tàbí lẹ́tà àtọwọ́dá tí a sọ pé ó ti ọwọ́ Paulu wá ti dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní Tẹsalonika ní ti bíbọ̀ Kristi lẹ́ẹ̀kejì. Bóyá ìdàrúdàpọ̀ yìí ló ń fa àìdẹ́kun inúnibíni tí wọ́n ní láti máa fi ara dà. Paulu kọ̀wé láti fún àwọn onígbàgbọ́ ní ìdánilójú pé Kristi yóò padà wá láti wá tù wọ́n nínú àti láti fi ìyà jẹ àwọn tó ń dààmú wọn (1.7,8). Ó tún sọ fún wọn pé ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ìdájọ́ ń bọ̀ kò ní bá wọn ní òjijì, ṣùgbọ́n àwọn oríṣìíríṣìí ìṣẹ̀lẹ̀ ni yóò ṣẹ̀ ṣáájú (2.3). Nítorí pé ìpadàbọ̀ Kristi dájú, àwọn onígbàgbọ́ gbọdọ̀ gbé ìgbé ayé tí kò ní àbùkù.
Nínú lẹ́tà yìí, ó tẹnumọ́ ìpinnu Ọlọ́run láti wó ìjọba Èṣù lulẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ lè jìyà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣètò ìtura àti èrè sílẹ̀ fún wọn. Ní ti àwọn tó kọ̀ láti gbọ́ ti Ọlọ́run, ìjìyà àti ìdájọ́ ń bọ́ wá sórí wọn. Paulu tẹnumọ́ ọ pé ó yẹ kí a máa rìn ní ìlànà tí Ọlọ́run fẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Tẹsalonika ni kò ṣe iṣẹ́ mọ́ nítorí pé wọ́n gbàgbọ́ pé Kristi kò ní pẹ́ ẹ dé mọ́. Èyí kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Paulu sọ̀rọ̀ lórí èyí. “Ẹni tí kò ṣiṣẹ́ kò ní jẹun.”
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìmúlọ́kànle nípa ìpadàbọ̀ Kristi 1.1-12.
ii. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kí ọjọ́ Olúwa tó dé 2.1-12.
iii. Àfikún àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú 2.1–3.5.
vi. Ìhùwàsí onígbàgbọ́ àti ìkíni ìgbẹ̀yìn 3.6-18.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

2 Tẹsalonika Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀