2 Ọba Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìtàn, àṣà, ẹ̀sìn ètò, ọrọ̀ ajé àti ètò ìṣèlú ilẹ̀ Israẹli. Ó sọ nípa àwọn ọba Israẹli àti ti Juda. Ó jẹ́ kí a mọ ìhà tí wọ́n kọ sí májẹ̀mú Ọlọ́run. Bákan náà ni ó sọ nípa àwọn wòlíì tó jẹ́ ẹni-àárín láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Ọlọ́run. Ó ń sọ nípa àwọn ọba tó kọ etí ikún sí májẹ̀mú Ọlọ́run bí àpẹẹrẹ “ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa: kò yà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀” (2Ọb 4.24). Bákan náà ni ó sọ nípa àwọn ọba tí ó ṣe ìgbọ́ràn sí májẹ̀mú Ọlọ́run bí àpẹẹrẹ, “Òun sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ó sì rìn ní ọ̀nà Dafidi baba rẹ̀ gbogbo, kò sì yípadà sí apá ọ̀tún tàbí sí apá òsì” (2Ọb 22.2).
Orúkọ àwọn ọba tí wọ́n jẹ ní Israẹli àti Juda ni a tò ní ẹsẹẹsẹ bí wọ́n ṣe jẹ tẹ̀lé ara wọn sí. Ó fẹ́ ka mọ iṣẹ́ ẹ̀sìn àwọn ọba wọ̀nyí ju ètò ìṣèjọba wọn lọ. Ó tẹpẹlẹ mọ́ ìdẹ̀ra náà àti ìnira ìgbà. Ìṣe baba àwọn ọba wọ̀nyí ni ó jẹ́ òdínwọ̀n fún àṣedán tàbí àìmọ̀ọ́ṣe wọn.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Wòlíì Elijah àti Eliṣa 1.1–18.15.
ii. Àwọn ọba Juda àti ti Israẹli 8.16–17.4.
iii. Ìṣubú Samaria 17.5-41.
iv. Láti orí Hesekiah dé Josiah 18.1–21.26.
v. Ìṣèjọba Josiah 22.1–23.30.
vi. Àwọn ọba Juda tó jẹ kẹ́yìn 23.31–24.20.
vii. Ìṣubú Jerusalẹmu 25.30.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

2 Ọba Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀