2 Ọba 2:9-10

2 Ọba 2:9-10 YCB

Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?” “Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn. “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”