Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run. Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú. Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára.
Kà 2 Kọrinti 7
Feti si 2 Kọrinti 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Kọrinti 7:8-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò