2 Kronika Ìfáàrà

Ìfáàrà
Àkọkún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ìdílé, ìran àti àwọn ẹ̀yà Israẹli tí a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣáájú ni ó jẹ ìwé yìí lógún. Ó sọ nípa ìtàn àwọn ọba Juda, bí wọ́n ṣe sin Ọlọ́run sí. Ó ṣe àsọkún nípa iṣẹ́ ẹ̀sìn àti ìṣe ọba Solomoni. Ọba Solomoni béèrè fún ọgbọ́n, Ọlọ́run fún un. Àwọn àṣekú iṣẹ́ ẹ̀sìn àti ìṣe Solomoni nípa ìgbésẹ̀ láti kọ́ tẹmpili tí ó sì yà á sí mímọ́, nípa ọlá àti ọlà Solomoni tí òkìkí rẹ̀ kàn kọjá orílẹ̀-èdè, tí àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn sì ń wá láti yọ́ ọ wò.
Ìjọba orílẹ̀-èdè Israẹli pín sí méjì, bẹ́ẹ̀ ni ọba sì di méjì pẹ̀lú. Jerusalẹmu jẹ́ olú ìlú fún Israẹli, Juda ń dá ọba tiwọn jẹ. Àwọn ọba wọ̀nyí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nítorí pé wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́. Wọ́n sì ń tẹ̀síwájú nípa sí sin àwọn òrìṣà tí baba wọn ń sìn, wọ́n ń fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì, wọ́n ń kọ́lé fún àwọn òrìṣà wọn. A kó wọn lọ sí ìgbèkùn ní orílẹ̀-èdè mìíràn láti mú wọn singbà. A dá wọ́n nídè kúrò ní ìgbèkùn padà sí orílẹ̀-èdè wọn.
Ọlọ́run fi àṣẹ láti kọ́ tẹmpili lélẹ̀ bí ó ṣe fi àṣẹ láti kọ́ àgọ́ lélẹ̀ nígbà ìṣáájú. Ó ṣe àtẹnumọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ìsọtẹ́lẹ̀, ìkìlọ̀, ìyànjú àti ìmọ̀ràn fún àwọn ọba tí ó jẹ ní Juda. Ó sọ nípa iṣẹ́ àwọn Lefi sí àwọn ọba, ìdílé, ìran àti àwọn ẹ̀yà Juda.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ètò ìjọba Solomoni 1–9.
ii. Orílẹ̀-èdè Israẹli pín 10.1–36.14.
iii. Ìkólọ sí ìgbèkùn àti ìpadàbọ̀ láti ìgbèkùn 36.15-23.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

2 Kronika Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀