1 Timotiu 6:9-12

1 Timotiu 6:9-12 YCB

Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.