1 Samuẹli Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé Samuẹli sọ nípa bí a ṣe dá ọba jíjẹ sílẹ̀ ní Israẹli. Kí òǹkọ̀wé yìí to ṣàlàyé ìyípadà kíákíá nínú ìṣètò Ìjọba Ọlọ́run, ó tí jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún wa bí ìwé náà ṣe jinlẹ̀ tó. Èkínní ohun tí ó fi yé wa ni ìbí, ìgbà ọ̀dọ́ àti ìpè Samuẹli. Ìwé yìí tún ṣàlàyé ìpín àwọn ọba méjì tó kọ́kọ́ jẹ ní ilẹ̀ Israẹli: Saulu àti Dafidi. Èkejì ni sísọ nípa àpótí ẹ̀rí. Èyí sọ nípa bì àwọn Filistini ṣe gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti mú ìbínú wá sórí gbogbo ìlú Filistini, bí àpótí ẹ̀rí yóò ṣe padà sí Israẹli. Ẹ̀kẹta ni bí Samuẹli ṣe jẹ́ onídàájọ́ àti olùdáǹdè. Nígbà tí Samuẹli sọ fun Israẹli pé kí wọn ronúpìwàdà àti kí wọn tún ìyàsímímọ́ wọn ṣe sí Olúwa, Olúwa fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn ọmọ Israẹli, Ó sì fún wọn ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ara Filistini. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Olúwa pàṣẹ fún Samuẹli láti fún àwọn ènìyàn náà ní ọba. A sì sọ fún Samuẹli pè kí ó fi òróró yan Saulu gẹ́gẹ́ bí ọba fún wọn.
Àwọn ọmọ Israẹli jà gba àpótí ẹ̀rí, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ ilẹ̀ Filistini fún ìparun ara wọn, òrìṣà wọn ilẹ̀ wọn àti ìlú wọn. Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí padà sí Israẹli. Èyí fi ìjẹgàba agbára Ọlọ́run lórí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Filistini hàn.
Israẹli béèrè fún ọba. Ọlọ́run pàṣẹ fún Samuẹli láti yan ọba fún Israẹli. Samuẹli fi Saulu jẹ ọba lórí Israẹli. Saulu ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Israẹli, ṣùgbọ́n ó sọ ìfẹ́ ara rẹ̀ lórí ogun tí ó jà pẹ̀lú àwọn Ameleki. Ojú Ọlọ́run kúrò ní ara Saulu. Saulu tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ. Samuẹli fi òróró yan Dafidi. Dafidi ṣẹ́gun Goliati àti àwọn ogun Filistini mìíràn. Saulu wá ọ̀nà láti pa Dafidi. Saulu padà wá pa ara rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìbí, ìpè àti ìṣèdájọ́ Samuẹli lórí ilé Eli 1–3.
ii. Samuẹli bí onídàájọ́ lórí Israẹli 4–6.
iii. Israẹli béèrè fún ọba 7–8.
iv. Samuẹli fi òróró yan Saulu sí ipò ọba 9.1–10.27.
v. Ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Saulu 11–15.
vi. A fi òróró yan Dafidi bí ọba tí ó jẹ lẹ́yìn Saulu 16.1-13.
vii. Rògbòdìyàn ní àárín Saulu àti Dafidi 16.14–30.31.
viii Ikú Saulu 31.1-13.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Samuẹli Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀