1 Peteru Ìfáárà

Ìfáárà
Aposteli Peteru kọ lẹ́tà yìí nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ dé òpin ayé rẹ̀, láti fi tu àwọn Júù tiwọn ti gbàgbọ́ nínú àti láti fi mú wọn ní ọkàn le pàápàá jùlọ àwọn tí ń gbé ní Asia. Ó tọ́ka sí i pé ìyà jíjẹ jẹ́ ara ìgbé ayé Kristi àti pé Ọlọ́run ti pèsè ẹ̀bùn tí kò le bàjẹ́ sílẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. Bí ẹnikẹ́ni bá ń rò láti padà sínú ẹ̀sìn àwọn Júù láti ba à bọ́ lọ́wọ́ inúnibíni àṣìṣe ńlá ni èyí jẹ́ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Peteru tọ́ka sí i pé nísinsin yìí ìjọ Ọlọ́run ní ààbò orílẹ̀-èdè àti ti oníṣẹ́ àlùfáà Ọlọ́run (2.9). Nítorí náà èrò kérò láti padà sínú ẹ̀sìn Júù jẹ́ asán. Peteru wá fi Kristi tó jìyà ṣe àpẹẹrẹ, ó rọ gbogbo àwọn Kristiani láti wà ní ìmúrasílẹ̀ fún irú ìrírí ti Kristi. Ẹ̀kọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ni ó parí lẹ́tà náà.
Àwọn Kristiani àkọ́kọ́ gbé ìgbé ayé tó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdojúkọ. Wọ́n fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Peteru fi ìdí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun múlẹ̀, ó fún wa ní ìpèníjà láti máa gbé ìgbé ayé mímọ́. Ó jẹ́ kí a rí Kristi bí òkúta ìyè, tí ìjìyà rẹ̀ sì jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. Ó sọ nípa ojúṣe ọkọ àti aya, ó sì gba àwọn alàgbà ní ìmọ̀ràn.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ògo ìgbàlà ti Kristi 1.1-25.
ii. Ìgbọràn Kristi 2.1-10.
iii. Fífi ìjìyà àti ìrírí Kristi ṣe àpẹẹrẹ 2.11-25.
iv. Ìgbé ayé Kristi nínú ilé àti gbogbo ayé 3.1-17.
v. Ìjìyà àti fífi Kristi ṣe àpẹẹrẹ 3.18-19.
vi. Iṣẹ́ Kristi àti ọ̀rọ̀ ìgbẹ̀yìn 5.1-14.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Peteru Ìfáárà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀