OLúWA sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú OLúWA, nítorí OLúWA fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú OLúWA; ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá. Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà. Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.” OLúWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu. Tún fi òróró yan Jehu ọmọ Nimṣi ní ọba lórí Israẹli, àti kí o fi òróró yan Eliṣa ọmọ Ṣafati, ará Abeli-Mehola ní wòlíì ní ipò rẹ. Jehu yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hasaeli, Eliṣa yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jehu. Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.”
Kà 1 Ọba 19
Feti si 1 Ọba 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 1 Ọba 19:11-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò