1 Johanu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Aposteli Johanu kọ ìwé yìí nígbà ogbó rẹ̀ sí àwọn Kristiani tó ṣe ọ̀wọ́n sí i, Ó pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀ kékeré, ó sì fún wọn ní ẹ̀kọ́ bí wọ́n ṣe lé gbé ìgbé ayé Kristiani, ó bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àtẹnumọ́ òtítọ́ pé Jesu wá nínú ara, àti pé ẹni tó bá mọ Jesu mọ Baba pẹ̀lú. Àwọn tí kò bá mọ Jesu kò mọ Baba, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ìfẹ́ baba. Àwọn onígbàgbọ́ ní òye ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ìgbé ayé wọn nítorí Ọlọ́run ní ìfẹ́ wọn, kò ní láti bẹ̀rù, bóyá ní ayé yìí tàbí ayé tí ń bọ̀.
Johanu tẹnumọ́ kókó ohun tó jẹ́ òtítọ́ nínú ìgbàgbọ́ nínú lẹ́tà rẹ̀ láti fi tu àwọn ọmọ rẹ̀ nínú, láti fi mú wọn lọ́kàn le nípa ti ẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ ìfẹ́, ìdáríjì, ìdàpọ̀ mímọ́, ìborí ẹ̀ṣẹ̀, ìdánilójú, mímọ́ àti iyè ayérayé ni ó wọ inú ara wọn ní ọ̀nà àrà pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run tó ń tàn sínú òkùnkùn ayé.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìdàpọ̀ mímọ́ láàrín Kristiani àti Ọlọ́run 1.1-10.
ii. Àṣẹ tuntun lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ 2.1-17.
iii. Ìkìlọ̀ lórí ìlòdì sí Kristiani àti ìwà búburú 2.18-29.
iv. Ìhùwàsí Kristi 3.1-24.
v. Àwọn olùkọ́ èké 4.1-6.
vi. Ìfẹ́ Ọlọ́run 4.7-21.
viii. Ìṣẹ́gun ti ìgbàgbọ́ 5.1-21.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Johanu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀