Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń gbé inú rẹ̀, àti Òun nínú wa, nítorí tí ó ti fi Ẹ̀mí rẹ̀ fún wa. Àwa tí rí, a sì jẹ́rìí pé Baba rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Ọmọ Ọlọ́run ni, Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú Ọlọ́run. Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́. Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.
Kà 1 Johanu 4
Feti si 1 Johanu 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 1 Johanu 4:13-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò