1 Kronika 24
24
Pínpín àwọn àlùfáà
1Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni:
Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. 2Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 3Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. 4A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìn-dínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari. 5Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.
6Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
7Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu,
èkejì sí Jedaiah,
8Ẹlẹ́kẹta sì ni Harimu,
ẹ̀kẹrin sì ní Ṣeorimu,
9Ẹ̀karùnún sì ni Malkiah,
ẹlẹ́kẹfà sì ni Mijamini,
10Èkeje sì ni Hakosi,
ẹlẹ́kẹjọ sí ni Abijah,
11Ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua,
ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,
12Ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu,
ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jakimu,
13Ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa,
ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,
14Ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah,
ẹ̀kẹrìn-dínlógún sì ni Immeri
15Ẹ̀kẹtà-dínlógún sì ni Hesiri,
èkejì-dínlógún sì ni Hafisesi,
16Ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah,
ogún sì ni Jeheskeli,
17Ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini,
ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,
18Ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah,
ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.
19Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.
Ìyókù nínú àwọn ọmọ Lefi
20Ìyókù àwọn ọmọ Lefi:
Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli
láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubueli; Jehdeiah.
21Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.
22Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti;
láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.
23Àwọn ọmọ Hebroni:
Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́kejì, Jahasieli ẹlẹ́kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́kẹrin.
24Àwọn ọmọ Usieli: Mika;
nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.
25Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi;
nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.
26Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi.
Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.
27Àwọn ọmọ Merari:
Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.
28Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
29Láti Kiṣi: Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.
30Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti.
Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
31Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèkéé.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
1 Kronika 24: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.