Sek 5

5
Ìran nípa Ìwé Kíká Tí Ó Ń Fò
1NIGBANA ni mo yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, iwe-kiká ti nfò.
2O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Emi si dahùn pe, mo ri iwe-kiká ti nfò; gigùn rẹ̀ jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹwa.
3O si wi fun mi pe, Eyi ni ègun ti o jade lọ si gbogbo ilẹ aiye: nitori gbogbo awọn ti o ba jale ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀; gbogbo awọn ti o ba si bura ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀.
4Emi o mu u jade, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, yio si wọ̀ inu ile olè lọ, ati inu ile ẹniti o ba fi orukọ mi bura eke: yio si wà li ãrin ile rẹ̀, yio si run u pẹlu igi ati okuta inu rẹ̀.
Ìran nípa Obinrin Tó Wà ninu Apẹ̀rẹ̀
5Angeli ti mba mi sọ̀rọ si jade lọ, o si wi fun mi pe, Gbe oju rẹ si oke nisisiyi, ki o si wò nkan yi ti o jade lọ.
6Mo si wipe, Kini nì? O si wipe, Eyi ni òṣuwọn efà ti o jade lọ. O si wipe, Eyi ni àworan ni gbogbo ilẹ aiye.
7Si kiyesi i, a gbe talenti ojé soke: obinrin kan si niyi ti o joko si ãrin òṣuwọn efa.
8O si wipe, Eyi ni ìwa-buburu. O si jù u si ãrin òṣuwọn efa: o si jù òṣuwọn ojé si ẹnu rẹ̀.
9Mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, obinrin meji jade wá, ẹfũfu si wà ninu iyẹ wọn; nitori nwọn ni iyẹ bi iyẹ àkọ: nwọn si gbe òṣuwọn efa na de agbedemeji aiye on ọrun.
10Mo si sọ fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ pe, Nibo ni awọn wọnyi ngbe òṣuwọn efa na lọ?
11O si wi fun mi pe, Lati kọ́ ọ ni ile ni ilẹ Ṣinari: a o si fi idi rẹ̀ mulẹ, a o si fi ka ori ipilẹ rẹ̀ nibẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Sek 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀