Sek 13
13
1LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́.
2Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o ke orukọ awọn òriṣa kuro ni ilẹ na, a kì yio si ranti wọn mọ: ati pẹlu emi o mu awọn woli ati awọn ẹmi aimọ́ kọja kuro ni ilẹ na.
3Yio si ṣe, nigbati ẹnikan yio sọtẹlẹ sibẹ̀, ni baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio wi fun u pe, Iwọ kì yio yè: nitori iwọ nsọ̀rọ eké li orukọ Oluwa: ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio gún u li agúnyọ nigbati o ba sọ̀tẹlẹ.
4Yio si ṣe li ọjọ na, oju yio tì awọn woli olukulukù nitori iran rẹ̀, nigbati on ba ti sọtẹlẹ; bẹ̃ni nwọn kì yio si wọ̀ aṣọ onirun lati tan ni jẹ:
5Ṣugbọn on o wipe, Emi kì iṣe woli, agbẹ̀ li emi; nitori enia li o ni mi bi iranṣẹ lati igbà ewe mi wá.
6Ẹnikan o si wi fun u pe, Ọgbẹ́ kini wọnyi li ọwọ rẹ? On o si dahùn pe, Wọnyi ni a ti ṣá mi ni ile awọn ọrẹ́ mi.
Àṣẹ pé kí Wọ́n Pa Àwọn Olùṣọ́-Agutan Ọlọrun
7Dide, iwọ idà, si olùṣọ-agùtan mi, ati si ẹniti iṣe ẹnikeji mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; kọlù olùṣọ-agùtan, awọn àgutan a si tuká: emi o si yi ọwọ mi si awọn kékèké.
8Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li Oluwa wi, a o ké apá meji ninu rẹ̀ kuro yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rẹ̀.
9Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sek 13: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.