Tit 3:1-3

Tit 3:1-3 YBCV

MÃ rán wọn leti lati mã tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati mã gbọ́ ti wọn, ati lati mã mura si iṣẹ rere gbogbo, Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia. Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.