Tit 3

3
Ìlànà nípa Ìwà Tí Ó Dára
1MÃ rán wọn leti lati mã tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati mã gbọ́ ti wọn, ati lati mã mura si iṣẹ rere gbogbo,
2Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia.
3Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.
4Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan,
5Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́,
6Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa;
7Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun.
8Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia.
9Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn.
10Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ;
11Ki o mọ̀ pe irú ẹni bẹ̃ ti yapa, o si ṣẹ̀, o dá ara rẹ̀ lẹbi.
Gbolohun Ìparí
12Nigbati mo ba rán Artema si ọ, tabi Tikiku, yara tọ̀ mi wá ni Nikopoli: nitori ibẹ ni mo ti pinnu lati lo akoko otutu.
13Pese daradara fun Sena amofin ati Apollo li ọ̀na àjo wọn, ki ohunkohun maṣe kù wọn kù.
14Ki awọn enia wa pẹlu si kọ́ lati mã ṣe iṣẹ rere fun ohun ti a kò le ṣe alaini, ki nwọn ki o má ba jẹ alaileso.
15Gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi kí ọ. Kí awọn ti o fẹ wa ninu igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Tit 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀