1
Tit 3:4-7
Bibeli Mimọ
Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan, Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́, Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa; Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Tit 3:4-7
2
Tit 3:1-2
MÃ rán wọn leti lati mã tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati mã gbọ́ ti wọn, ati lati mã mura si iṣẹ rere gbogbo, Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia.
Ṣàwárí Tit 3:1-2
3
Tit 3:9
Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn.
Ṣàwárí Tit 3:9
4
Tit 3:10
Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ
Ṣàwárí Tit 3:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò