Tit 1

1
Ìkíni
1PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun,
2Ni ireti ìye ainipẹkun, ti Ọlọrun, Ẹniti kò le ṣèké, ti ṣe ileri ṣaju ipilẹṣẹ aiye;
3Ṣugbọn ni akokò tirẹ̀ o fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn ninu iwasu, ti a fi le mi lọwọ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa;
4Si Titu, ọmọ mi nitõtọ nipa igbagbọ́ ti iṣe ti gbogbo enia: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá ati Kristi Jesu Olugbala wa.
Iṣẹ́ Titu ní Kirete
5Nitori idi eyi ni mo ṣe fi ọ silẹ ni Krete, ki iwọ ki o le ṣe eto ohun ti o kù, ki o si yan awọn alagba ni olukuluku ilu, bi mo ti paṣẹ fun ọ.
6Bi ẹnikan ba ṣe alailẹgan, ọkọ aya kan, ti o ni ọmọ ti o gbagbọ́, ti a kò fi sùn fun wọbia, ti nwọn kò si jẹ alagidi.
7Nitori o yẹ ki biṣopu jẹ alailẹgàn, bi iriju Ọlọrun; ki o má jẹ aṣe-tinu-ẹni, oninu-fùfu, ọmuti, aluni, olojukokoro;
8Bikoṣe olufẹ alejò ṣiṣe, olufẹ awọn enia rere, alairekọja, olõtọ, ẹni mimọ́, ẹni iwọntunwọnsi;
9Ti o ndì ọ̀rọ otitọ mu ṣinṣin eyiti iṣe gẹgẹ bi ẹ̀kọ́, ki on ki o le mã gbani-niyanju ninu ẹ̀kọ́ ti o yè kõro, ki o si le mã da awọn asọrọ-odi lẹbi.
10Nitoripe ọpọlọpọ awọn alagídi, awọn asọ̀rọ asan, ati awọn ẹlẹtàn ni mbẹ, papa awọn ti ikọla:
11Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.
12Ọkan ninu wọn, ani woli awọn tikarawọn, wipe, Eke ni awọn ará Krete nigbagbogbo, ẹranko buburu, ọlẹ alajẹki.
13Otitọ li ẹrí yi. Nitorina bá wọn wi gidigidi, ki nwọn ki o le yè kõro ni igbagbọ́;
14Ki nwọn máṣe fiyesi ìtan lasan ti awọn Ju, ati ofin awọn enia ti nwọn yipada kuro ninu otitọ.
15Ohun gbogbo ni o mọ́ fun awọn ẹniti o mọ́, ṣugbọn fun awọn ti a sọ di ẹlẹgbin ati awọn alaigbagbọ́ kò si ohun ti o mọ́; ṣugbọn ati inu ati ẹ̀ri-ọkan wọn li a sọ di ẹgbin.
16Nwọn jẹwọ pe nwọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ nwọn nsẹ́ ẹ, nwọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilari.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Tit 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa