Rut 2:1-16

Rut 2:1-16 YBCV

NAOMI si ní ibatan ọkọ rẹ̀ kan, ọlọrọ̀ pupọ̀, ni idile Elimeleki; orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Boasi. Rutu ara Moabu si wi fun Naomi pe, Jẹ ki emi lọ si oko nisisiyi, ki emi si ma peṣẹ́-ọkà lẹhin ẹniti emi o ri õre-ọfẹ́ li oju rẹ̀. On si wipe, Lọ, ọmọbinrin mi. On si lọ, o si dé oko, o si peṣẹ́-ọkà lẹhin awọn olukore: o si wa jẹ pe apa oko ti o bọ si jẹ́ ti Boasi, ti iṣe ibatan Elimeleki. Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ. Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi? Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile. Nigbana ni Boasi wi fun Rutu pe, Iwọ kò gbọ́, ọmọbinrin mi? Máṣe lọ peṣẹ́-ọkà li oko miran, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe re ihin kọja, ṣugbọn ki o faramọ́ awọn ọmọbinrin mi nihin. Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn. Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi? Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí. Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle. Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin. Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ. Nigbati o si dide lati peṣẹ́-ọkà, Boasi si paṣẹ fun awọn ọmọkunrin rẹ̀, wipe, Ẹ jẹ ki o peṣẹ́-ọkà ani ninu awọn ití, ẹ má si ṣe bá a wi. Ki ẹ si yọ diẹ ninu ití fun u, ki ẹ si fi i silẹ, ki ẹ si jẹ ki o ṣà a, ẹ má si ṣe bá a wi.