Rut 2:1-16

Rut 2:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

NAOMI si ní ibatan ọkọ rẹ̀ kan, ọlọrọ̀ pupọ̀, ni idile Elimeleki; orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Boasi. Rutu ara Moabu si wi fun Naomi pe, Jẹ ki emi lọ si oko nisisiyi, ki emi si ma peṣẹ́-ọkà lẹhin ẹniti emi o ri õre-ọfẹ́ li oju rẹ̀. On si wipe, Lọ, ọmọbinrin mi. On si lọ, o si dé oko, o si peṣẹ́-ọkà lẹhin awọn olukore: o si wa jẹ pe apa oko ti o bọ si jẹ́ ti Boasi, ti iṣe ibatan Elimeleki. Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ. Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi? Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile. Nigbana ni Boasi wi fun Rutu pe, Iwọ kò gbọ́, ọmọbinrin mi? Máṣe lọ peṣẹ́-ọkà li oko miran, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe re ihin kọja, ṣugbọn ki o faramọ́ awọn ọmọbinrin mi nihin. Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn. Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi? Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí. Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle. Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin. Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ. Nigbati o si dide lati peṣẹ́-ọkà, Boasi si paṣẹ fun awọn ọmọkunrin rẹ̀, wipe, Ẹ jẹ ki o peṣẹ́-ọkà ani ninu awọn ití, ẹ má si ṣe bá a wi. Ki ẹ si yọ diẹ ninu ití fun u, ki ẹ si fi i silẹ, ki ẹ si jẹ ki o ṣà a, ẹ má si ṣe bá a wi.

Rut 2:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò yìí, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà ninu ìdílé Elimeleki, ẹbí kan náà ni ọkunrin yìí ati ọkọ Naomi. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi. Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.” Rutu bá gbéra, ó lọ sí oko ọkà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà gbàgbé sílẹ̀. Oko tí ó lọ jẹ́ ti Boasi, ìbátan Elimeleki. Kò pẹ́ pupọ ni Boasi náà dé láti Bẹtilẹhẹmu. Ó kí àwọn tí wọn ń kórè ọkà, ó ní, “Kí OLUWA wà pẹlu yín.” Àwọn náà dáhùn pé, “Kí OLUWA bukun ọ.” Boasi bèèrè lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ́ alákòóso àwọn tí ń kórè, ó ní, “Ọmọ ta ni ọmọbinrin yìí?” Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó bẹ̀ wá pé kí á jọ̀wọ́ kí á fún òun ní ààyè láti máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọn ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀. Láti àárọ̀ tí ó ti dé, ni ó ti ń ṣiṣẹ́ títí di àkókò yìí láìsinmi, bí ó ti wù kí ó mọ.” Boasi bá pe Rutu, ó ní, “Gbọ́, ọmọ mi, má lọ sí oko ẹlòmíràn láti ṣa ọkà, má kúrò ní oko yìí, ṣugbọn faramọ́ àwọn ọmọbinrin mi. Oko tí wọn ń kórè rẹ̀ yìí ni kí o kọjú sí, kí o sì máa tẹ̀lé wọn. Mo ti kìlọ̀ fún àwọn ọdọmọkunrin wọnyi pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Nígbà tí òùgnbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ sí ìdí àmù, kí o sì mu ninu omi tí àwọn ọdọmọkunrin wọnyi bá pọn.” Rutu bá wólẹ̀ ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Mo dúpẹ́ pé mo rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ tó báyìí, o sì ṣe akiyesi mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni mí.” Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí. OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.” Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.” Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Boasi pe Rutu, ó ní, “Wá jẹun, kí o fi òkèlè rẹ bọ inú ọtí kíkan.” Rutu bá jókòó lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ń kórè ọkà, Boasi gbé ọkà yíyan nawọ́ sí i; ó sì jẹ àjẹyó ati àjẹṣẹ́kù. Nígbà tí Rutu dìde, láti tún máa ṣa ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí ó máa ṣa ọkà láàrin àwọn ìtí ọkà tí ẹ dì jọ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu. Kí ẹ tilẹ̀ fa ọkà yọ fún un ninu ìtí, kí ẹ sì tún fi í sílẹ̀ láti ṣa ọkà, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọ ọ́ lẹ́nu.”

Rut 2:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Naomi ní ìbátan kan láti ìdílé Elimeleki ọkọ rẹ̀, aláàánú ọlọ́rọ̀, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi. Rutu ará Moabu sì wí fún Naomi pé, “Jẹ́ kí èmi kí ó lọ sí inú oko láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí èmi yóò bá ojúrere rẹ̀ pàdé.” Naomi sì sọ fún un pé, “Máa lọ, ọmọbìnrin mi.” Rutu sì jáde lọ láti ṣá ọkà tí àwọn olùkórè fi sílẹ̀ lẹ́yìn wọn. Ó wá jẹ́ wí pé inú oko Boasi tí ó ti ìdílé Elimeleki wá ni ó lọ láìmọ̀-ọ́n-mọ̀. Nígbà náà ni Boasi dé láti Bẹtilẹhẹmu tí ó sì kí àwọn olùkórè wí pé, “Kí OLúWA wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kí OLúWA bùkún fún ọ.” Boasi sì béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùkórè wí pé, “Ti ta ni ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn?” Ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olórí àwọn olùkórè náà sì fèsì pé, “Ọ̀dọ́mọbìnrin ará Moabu tí ó tẹ̀lé Naomi wá láti ilẹ̀ Moabu ni. Ó sọ wí pé, ‘Kí ń jọ̀wọ́ jẹ́ kí òun máa ṣá ọkà lẹ́yìn àwọn olùkórè.’ Ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ kárakára láti òwúrọ̀ títí di ìsinsin yìí nínú oko àyàfi ìgbà tí ó lọ láti sinmi fún ìgbà díẹ̀ lábẹ́ ibojì.” Nígbà náà ni Boasi sọ fún Rutu pé, “Gbọ́ ọmọbìnrin mi, má ṣe lọ sí oko mìíràn láti ṣá ọkà, má sì ṣe kúrò ní ibi. Dúró níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi. Wo ibi tí wọ́n ti ń kórè kí o sì máa tẹ̀lé àwọn obìnrin. Mo ti pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n má ṣe fi ọwọ́ kàn ọ́. Nígbàkúgbà tí òǹgbẹ bá sì ń gbẹ ọ́, lọ kí ó sì mu omi nínú àmù èyí tí àwọn ọkùnrin ti pọn omi sí nínú.” Rutu wólẹ̀, ó sì wí fún Boasi pé, “Èéṣe tí èmi fi bá ojúrere rẹ pàdé tó báyìí, tí o sì kíyèsi mi, èmi àjèjì àti àlejò?” Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Kí OLúWA kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ OLúWA Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.” Rutu sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ síwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.” Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Boasi sọ fún Rutu pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yìí kí o sì fi run wáìnì kíkan.” Òun sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Boasi sì fún un ní ọkà yíyan. Òun sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù. Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣá ọkà, Boasi pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàrín oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́. Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣá, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.”