Rom 7:17-25

Rom 7:17-25 YBCV

Njẹ nisisiyi kì iṣe emi li o nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti o ngbe inu mi. Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri. Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti ngbe inu mi. Njẹ mo ri niti ofin pe, bi emi ti nfẹ lati mã ṣe rere, buburu a ma wà lọdọ mi. Inu mi sá dùn si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu: Ṣugbọn mo ri ofin miran ninu awọn ẹ̀ya ara mi, ti mba ofin inu mi jagun ti o si ndì mi ni igbekun wá fun ofin ẹ̀ṣẹ, ti o mbẹ ninu awọn ẹ̀ya ara mi. Emi ẹni òṣi! tani yio gbà mi lọwọ ara ikú yi? Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa. Njẹ nitorina emi tikarami nfi inu jọsin fun ofin Ọlọrun; ṣugbọn mo nfi ara jọsin fun ofin ẹ̀ṣẹ.