Nitori o ṣọ̀wọn ki ẹnikan ki o to kú fun olododo: ṣugbọn fun enia rere boya ẹlomiran tilẹ le dába ati kú. Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa. Melomelo si ni, ti a da wa lare nisisiyi nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, li a o gbà wa là kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ̀. Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀. Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa nṣogo ninu Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti awa ti ri ìlaja gbà nisisiyi. Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀
Kà Rom 5
Feti si Rom 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 5:7-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò