Rom 3:9-31

Rom 3:9-31 YBCV

Njẹ ki ha ni? awa ha san jù wọn bi? Kò ri bẹ̃ rara: nitori a ti fihan ṣaju pe ati awọn Ju ati awọn Hellene, gbogbo nwọn li o wà labẹ ẹ̀ṣẹ; Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan. Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn. Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun. Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá. Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli; Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ: Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun; Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́. Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́. Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin. Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu: Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn. Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ.