Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Herme, ati awọn arakunrin ti o wà pẹlu wọn.
Ẹ kí Filologu, ati Julia, Nereu, ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa, ati gbogbo awọn enia mimọ́ ti o wà pẹlu wọn.
Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ ki ara nyin. Gbogbo ijọ Kristi kí nyin.
Ará, emi si bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣọ awọn ti nṣe ìyapa, ati awọn ti nmu ohun ikọsẹ̀ wá lodi si ẹkọ́ ti ẹnyin kọ́; ẹ si kuro ni isọ wọn.
Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà.
Nitori igbagbọ́ nyin tàn kalẹ de ìbi gbogbo. Nitorina mo ni ayọ̀ lori nyin: ṣugbọn emi fẹ ki ẹ jẹ ọlọgbọn si ohun ti o ṣe rere, ki ẹ si ṣe òpe si ohun ti iṣe buburu.
Ọlọrun alafia yio si tẹ̀ Satani mọlẹ li atẹlẹsẹ nyin ni lọ̃lọ. Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu nyin. Amin.
Timotiu, alabaṣiṣẹ mi, ati Lukiu, ati Jasoni, ati Sosipateru, awọn ibatan mi, ki nyin.
Emi Tertiu ti nkọ Episteli yi, kí nyin ninu Oluwa.
Gaiu, bãle mi, ati ti gbogbo ijọ, ki nyin. Erastu, olutọju iṣura ilu, kí nyin, ati Kuartu arakunrin.
Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.
Njẹ fun ẹniti o li agbara lati fi ẹsẹ nyin mulẹ gẹgẹ bi ihinrere mi ati iwasu Jesu Kristi, gẹgẹ bi iṣipaya ohun ijinlẹ, ti a ti pamọ́ lati igba aiyeraiye,
Ti a si nfihàn nisisiyi, ati nipa iwe-mimọ́ awọn woli, gẹgẹ bi ofin Ọlọrun aiyeraiye, ti a nfihàn fun gbogbo orilẹ-ède si igbọràn igbagbọ́:
Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo nipasẹ Jesu Kristi li ogo wà fun lailai. Amin.