Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé. Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wà ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o máṣe rò ara rẹ̀ jù bi o ti yẹ ni rirò lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntun-wọnsìn, bi Ọlọrun ti fi ìwọn igbagbọ́ fun olukuluku. Nitori gẹgẹ bi awa ti li ẹ̀ya pipọ ninu ara kan, ti gbogbo ẹ̀ya kò si ni iṣẹ kanna: Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀. Njẹ bi awa si ti nri ọ̀tọ ọ̀tọ ẹ̀bun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a mã sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọn igbagbọ́; Tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹniti nkọ́ni, ki o kọjusi kíkọ́; Tabi ẹniti o ngbàni niyanju, si igbiyanju: ẹniti o nfi funni ki o mã fi inu kan ṣe e; ẹniti nṣe olori, ki o mã ṣe e li oju mejeji; ẹniti nṣãnu, ki o mã fi inu didùn ṣe e.
Kà Rom 12
Feti si Rom 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 12:2-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò