Ifi 6:12-17

Ifi 6:12-17 YBCV

Nigbati o si ṣí èdidi kẹfa mo si ri, si kiyesi i, ìṣẹlẹ nla kan ṣẹ̀; õrùn si dudu bi aṣọ-ọfọ onirun, oṣupa si dabi ẹ̀jẹ; Awọn irawọ oju ọrun si ṣubu silẹ gẹgẹ bi igi ọpọtọ iti rẹ̀ àigbó eso rẹ̀ dànu, nigbati ẹfũfu nla ba mì i. A si ká ọ̀run kuro bi iwe ti a ká; ati olukuluku oke ati erekuṣu li a si ṣí kuro ni ipò wọn. Awọn ọba aiye ati awọn ọlọlá ati awọn olori ogun, ati awọn ọlọrọ̀ ati awọn alagbara, ati olukuluku ẹrú, ati olukuluku omnira, si fi ara wọn pamọ́ ninu ihò-ilẹ, ati ninu àpata ori òke: Nwọn si nwi fun awọn òke ati awọn àpata na pe, Ẹ wólu wa, ki ẹ si fi wa pamọ́ kuro loju ẹniti o joko lori itẹ́, ati kuro ninu ibinu Ọdọ-Agutan na: Nitori ọjọ nla ibinu wọn de; tani si le duro?