Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ati bi iró omi pupọ̀, ati bi iró ãrá nlanla, nwipe Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, njọba.
Ẹ jẹ ki a yọ̀, ki inu wa ki o si dùn gidigidi, ki a si fi ogo fun u: nitoripe igbeyawo Ọdọ-Agutan de, aya rẹ̀ si ti mura tan.
On ni a si fifun pe ki o wọ aṣọ ọgbọ wíwẹ ti o funfun gbõ: nitoripe aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣẹ ododo awọn enia mimọ́.
O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Ibukún ni fun awọn ti a pè si àse-alẹ igbeyawo Ọdọ-Agutan. O si wi fun mi pe, Wọnyi ni ọ̀rọ otitọ Ọlọrun.
Mo si wolẹ li ẹsẹ rẹ̀ lati foribalẹ fun u. O si wi fun mi pe, Wò o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ ti nwọn di ẹrí Jesu mu: foribalẹ fun Ọlọrun: nitoripe ẹrí Jesu li ẹmí isọtẹlẹ.
Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun.
Oju rẹ̀ dabi ọwọ iná, ati li ori rẹ̀ ni ade pupọ̀ wà; o si ni orukọ kan ti a kọ, ti ẹnikẹni kò mọ̀, bikoṣe on tikararẹ̀.
A si wọ̀ ọ li aṣọ ti a tẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ: a si npè orukọ rẹ̀ ni Ọ̀rọ Ọlọrun.
Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun.
Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mã fi ṣá awọn orilẹ-ède: on o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare.
O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA.
Mo si ri angẹli kan duro ninu õrùn; o si fi ohùn rara kigbe, o nwi fun gbogbo awọn ẹiyẹ ti nfò li agbedemeji ọrun pe, Ẹ wá, ẹ si kó ara nyin jọ pọ̀ si àse-alẹ nla Ọlọrun;
Ki ẹnyin ki o le jẹ ẹran-ara awọn ọba, ati ẹran-ara awọn olori ogun, ati ẹran-ara awọn enia alagbara, ati ẹran awọn ẹṣin, ati ti awọn ti o joko lori wọn, ati ẹran-ara enia gbogbo, ati ti omnira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgba.
Mo si ri ẹranko na ati awọn ọba aiye, ati awọn ogun wọn ti a gbájọ lati ba ẹniti o joko lori ẹṣin na ati ogun rẹ̀ jagun.
A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ̀, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ̀, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lãye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jò.
Awọn iyokù li a si fi idà ẹniti o joko lori ẹṣin na pa, ani idà ti o ti ẹnu rẹ̀ jade: gbogbo awọn ẹiyẹ si ti ipa ẹran-ara wọn yó.