Ifi 14

14
Orin Àwọn Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan
1Mo si wò, si kiyesi i, Ọdọ-Agutan na duro lori òke Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, nwọn ni orukọ rẹ̀, ati orukọ Baba rẹ̀ ti a kọ si iwaju wọn.
2Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá, bi ariwo omi pupọ̀, ati bi sisán ãrá nla: mo si gbọ́ awọn aludùru, nwọn nlù dùru wọn:
3Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá.
4Awọn wọnyi li a kò fi obinrin sọ di ẽri; nitoripe wundia ni nwọn. Awọn wọnyi ni ntọ̀ Ọdọ-Agutan na lẹhin nibikibi ti o ba nlọ. Awọn wọnyi li a rà pada lati inu awọn enia wá, nwọn jẹ́ akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan na.
5A kò si ri eke li ẹnu wọn, nwọn jẹ alailabuku.
Iṣẹ́ tí Àwọn Angẹli Mẹta Jẹ́
6Mo si ri angẹli miran nfò li agbedemeji ọrun, ti on ti ihinrere ainipẹkun lati wãsu fun awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, ati fun gbogbo orilẹ, ati ẹya, ati ède, ati enia,
7O nwi li ohùn rara pe, Ẹ bẹ̀ru Ọlọrun, ki ẹ si fi ogo fun u; nitoriti wakati idajọ rẹ̀ de: ẹ si foribalẹ fun ẹniti o dá ọrun, on aiye, ati okun, ati awọn orisun omi.
8Angẹli miran si tẹ̀le e, o nwipe, Babiloni wó, Babiloni ti o tobi nì wó, eyiti o ti nmú gbogbo orilẹ-ède mu ninu ọti-waini ibinu àgbere rẹ̀.
9Angẹli kẹta si tẹle wọn, o nwi li ohùn rara pe, Bi ẹnikẹni ba nforibalẹ fun ẹranko nì, ati aworan rẹ̀, ti o si gbà àmi si iwaju rẹ̀ tabi si ọwọ́-rẹ̀,
10On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rẹ̀; a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan:
11Ẹ̃fin oró wọn si nlọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru, awọn ti nforibalẹ fun ẹranko na ati fun aworan rẹ̀, ati ẹnikẹni ti o ba si gbà àmi orukọ rẹ̀.
12Nihin ni sũru awọn enia mimọ́ gbé wà: awọn ti npa ofin Ọlọrun ati igbagbọ́ Jesu mọ́.
13Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá nwi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Alabukún fun li awọn okú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhin lọ: Bẹni, li Ẹmí wi, ki nwọn ki o le simi kuro ninu lãlã wọn, nitori iṣẹ wọn ntọ̀ wọn lẹhin.
Ìkórè Ayé
14Mo si wò, si kiyesi i, awọsanma funfun kan, ati lori awọsanma na ẹnikan joko ti o dabi Ọmọ-enia, ti on ti ade wura li ori rẹ̀, ati dòjé mimú li ọwọ́ rẹ̀.
15Angẹli miran si ti inu tẹmpili jade wá ti nke li ohùn rara si ẹniti o joko lori awọsanma pe, Tẹ̀ doje rẹ bọ̀ ọ, ki o si mã kore: nitori akokò ati kore de, nitori ikorè aiye ti gbó tan.
16Ẹniti o joko lori awọsanma na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ori ilẹ aiye; a si ṣe ikore ilẹ aiye.
17Angẹli miran si ti inu tẹmpili ti mbẹ li ọrun jade wá, ti on ti doje mimu.
18Angẹli miran si ti ibi pẹpẹ jade wá, ti o ni agbara lori iná; o si ke li ohùn rara si ẹniti o ni doje mimu, wipe, Tẹ̀ doje rẹ mimu bọ̀ ọ, ki o si rẹ́ awọn idi ajara aiye, nitori awọn eso rẹ̀ ti pọ́n.
19Angẹli na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ilẹ aiye, o si ké ajara ilẹ aiye, o si kó o lọ sinu ifúnti, ifúnti nla ibinu Ọlọrun.
20A si tẹ̀ ifúnti na lẹhin odi ilu na, ẹ̀jẹ si ti inu ifúnti na jade, ani ti o tó okùn ijanu ẹṣin jinna to ẹgbẹjọ furlongi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ifi 14: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀