O si duro lori iyanrìn okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá, o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀ na ni orukọ ọrọ-odi. Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀ si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla. Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ̀ bi ẹnipe a sá a pa, a si ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ̀ na san, gbogbo aiye si fi iyanu tẹle ẹranko na. Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? tali o si le ba a jagun? A si fun u li ẹnu lati mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu mejilelogoji. O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun. A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ. Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye. Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́. Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ́ awọn enia mimọ́ gbé wà.
Kà Ifi 13
Feti si Ifi 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 13:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò