Ifi 12

12
Obinrin kan ati Ẹranko Ewèlè
1ÀMI nla kan si hàn li ọrun; obinrin kan ti a fi õrùn wọ̀ li aṣọ, oṣupa si mbẹ labẹ ẹsẹ rẹ̀, ade onirawọ mejila si mbẹ li ori rẹ̀:
2O si lóyun, o si kigbe ni irọbi, o si wà ni irora ati bimọ.
3Àmi miran si hàn li ọrun; si kiyesi i, dragoni pupa nla kan, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati adé meje li ori rẹ̀.
4Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o si ju wọn si ilẹ aiye, dragoni na si duro niwaju obinrin na ti o fẹ bímọ, pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ.
5O si bí ọmọkunrin kan ti yio fi ọpá irin ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀.
6Obinrin na si sá lọ si aginjù, nibiti a gbé ti pèse àye silẹ dè e lati ọwọ́ Ọlọrun wá, pe ki nwọn ki o mã bọ́ ọ nibẹ̀ li ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta.
7Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀.
8Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun.
9A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.
10Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru.
11Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú.
12Nitorina ẹ mã yọ̀, ẹnyin ọrun, ati ẹnyin ti ngbé inu wọn. Egbé ni fun aiye ati fun okun! nitori Èṣu sọkalẹ tọ̀ nyin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgba kukuru ṣá li on ni.
13Nigbati dragoni na ri pe a lé on lọ si ilẹ aiye, o ṣe inunibini si obinrin ti o bí ọmọkunrin na.
14A si fi apá iyẹ́ meji ti idì nla na fun obinrin na, pe ki o fò lọ si aginjù, si ipò rẹ̀, nibiti a gbé bọ́ ọ fun akoko kan ati fun awọn akoko, ati fun idaji akoko kuro lọdọ ejò na.
15Ejò na si tú omi jade lati ẹnu rẹ̀ wá bi odo nla sẹhin obinrin na, ki o le mu ki ìṣan omi na gbá a lọ.
16Ilẹ si ràn obinrin na lọwọ, ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si fi ìṣan omi na mu, ti dragoni na tú jade lati ẹnu rẹ̀ wá.
17Dragoni na si binu gidigidi si obinrin na, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyokù jagun, ti nwọn npa ofin Ọlọrun mọ́, ti nwọn si di ẹrí Jesu mu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ifi 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa