Ifi 12:1-10

Ifi 12:1-10 YBCV

ÀMI nla kan si hàn li ọrun; obinrin kan ti a fi õrùn wọ̀ li aṣọ, oṣupa si mbẹ labẹ ẹsẹ rẹ̀, ade onirawọ mejila si mbẹ li ori rẹ̀: O si lóyun, o si kigbe ni irọbi, o si wà ni irora ati bimọ. Àmi miran si hàn li ọrun; si kiyesi i, dragoni pupa nla kan, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati adé meje li ori rẹ̀. Ìru rẹ̀ si wọ́ idamẹta awọn irawọ, o si ju wọn si ilẹ aiye, dragoni na si duro niwaju obinrin na ti o fẹ bímọ, pe nigbati o ba bí, ki o le pa ọmọ rẹ̀ jẹ. O si bí ọmọkunrin kan ti yio fi ọpá irin ṣe akoso gbogbo awọn orilẹ-ède: a si gbà ọmọ rẹ̀ lọ soke si ọdọ Ọlọrun, ati si ori itẹ́ rẹ̀. Obinrin na si sá lọ si aginjù, nibiti a gbé ti pèse àye silẹ dè e lati ọwọ́ Ọlọrun wá, pe ki nwọn ki o mã bọ́ ọ nibẹ̀ li ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta. Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀. Nwọn kò si le ṣẹgun; bẹ̃ni a kò si ri ipo wọn mọ́ li ọrun. A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀. Mo si gbọ́ ohùn rara li ọrun, nwipe, Nigbayi ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti lé olufisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsán ati loru.