Ifi 10

10
Angẹli ati Ìwé-kíká Kékeré
1MO si ri angẹli miran alagbara o nti ọrun sọkalẹ wá, a fi awọsanma wọ̀ ọ li aṣọ: oṣumare si mbẹ li ori rẹ̀, oju rẹ̀ si dabi õrùn, ati ẹsẹ rẹ̀ bi ọwọ̀n iná:
2O si ni iwe kekere kàn ti a ṣi li ọwọ́ rẹ̀: o si fi ẹsẹ rẹ̀ ọtun le okun, ati ẹsẹ rẹ̀ òsi le ilẹ,
3O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun.
4Nigbati awọn ãrá meje na fọhun, mo mura ati kọwe: mo si gbọ́ ohùn lati ọrun wá nwi fun mi pe, Fi èdidi dí ohun ti awọn ãrá meje na sọ, má si ṣe kọ wọn silẹ.
5Angẹli na ti mo ri ti o duro lori okun ati lori ilẹ, si gbé ọwọ́ rẹ̀ si oke ọrun,
6O si fi ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai búra, ẹniti o dá ọrun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ aiye, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, ati okun, ati ohun ti mbẹ ninu rẹ̀, pe ìgba kì yio si mọ́:
7Ṣugbọn li ọjọ ohùn angẹli keje, nigbati yio ba fun ipe, nigbana li ohun ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi ihinrere ti o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli.
8Ohùn na ti mo gbọ́ lati ọrun wá tún mba mi sọrọ, o si wipe, Lọ, gbà iwe ti o ṣí nì lọwọ angẹli ti o duro lori okun ati lori ilẹ.
9Mo si tọ̀ angẹli na lọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni iwe kekere nì. O si wi fun mi pe, Gbà ki o si jẹ ẹ tan; yio mu inu rẹ korò, ṣugbọn li ẹnu rẹ yio dabi oyin.
10Mo si gbà iwe kekere na li ọwọ́ angẹli na, mo si jẹ ẹ tan; o si dùn li ẹnu mi bi oyin: bi mo si ti jẹ ẹ tan, inu mi korò.
11A si wi fun mi pe, Iwọ o tún sọ asọtẹlẹ lori ọpọlọpọ enia, ati orilẹ, ati ède, ati awọn ọba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Ifi 10: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀