O. Daf Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé tí à ń pè ní Orin Dafidi ni ìwé orin ati ìwé adura ninu Bibeli. Ọpọlọpọ ọdún ni àwọn tí ó kọ orin inú ìwé náà fi kọ ọ́ sílẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe àkójọpọ̀ wọn, wọ́n sì ń lò ó fún ìjọ́sìn. Nígbà tí ó yá, wọ́n fi àwọn orin náà kún Ìwé Mímọ́ wọn.
Oríṣìíríṣìí ni àwọn orin ẹ̀sìn wọnyi: orin ìyìn ati orin ìsìn, orin adura ati ìrànlọ́wọ́, orin ààbò ati ìgbàlà; orin ẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, orin ọpẹ́ fún ibukun Ọlọrun, ati ti ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun pé kí ó jẹ àwọn ọ̀tá ẹni níyà. Àwọn adura yìí wà fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tabi orílẹ̀-èdè. Àwọn mìíràn jẹ́ ti ẹ̀dùn ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan, àwọn yòókù sì jẹ́ ti àìní ati èrò ọkàn gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.
Jesu lò lára àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Orin Dafidi , àwọn tí wọ́n kọ ìwé Majẹmu Titun náà sì ṣe àmúlò rẹ̀. Láti ìgbà tí ìjọ Kristi ti bẹ̀rẹ̀ ni ìwé náà sì ti di ìwé ìṣúra fún ìjọ́sìn.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀nà marun-un ni a pín aadọjọ Orin Dafidi náà sí:
Orin Dafidi 1—41
Orin Dafidi 42—72
Orin Dafidi 73—89
Orin Dafidi 90—106
Orin Dafidi 107—150

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa